15 Èyí ni ìròyìn nípa àwọn tí Ọba Sólómọ́nì ní kó máa ṣiṣẹ́ fún òun+ láti kọ́ ilé Jèhófà,+ ilé* tirẹ̀, Òkìtì,*+ ògiri Jerúsálẹ́mù, Hásórì,+ Mẹ́gídò+ àti Gésérì.+
5 Yàtọ̀ síyẹn, ó rí i dájú pé òun tún gbogbo ògiri tó wó lulẹ̀ mọ, ó sì kọ́ àwọn ilé gogoro lé e lórí, ó tún mọ ògiri míì síta. Bákan náà, ó ṣàtúnṣe Òkìtì*+ tó wà ní Ìlú Dáfídì, ó sì ṣe ohun ìjà* tó pọ̀ gan-an àti àwọn apata.