-
1 Sámúẹ́lì 19:2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
2 Nítorí pé Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ Dáfídì+ gan-an, ó sọ fún Dáfídì pé: “Sọ́ọ̀lù bàbá mi fẹ́ pa ọ́. Jọ̀wọ́ múra láàárọ̀ ọ̀la, sá lọ sí ibi ìkọ̀kọ̀ kan, kí o sì fara pa mọ́ síbẹ̀.
-
-
1 Sámúẹ́lì 20:41Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
41 Nígbà tí ìránṣẹ́ náà lọ, Dáfídì dìde láti ibì kan tó wà nítòsí lápá gúúsù. Ó wá kúnlẹ̀, ó sì tẹrí ba mọ́lẹ̀ nígbà mẹ́ta, wọ́n fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu, wọ́n sì sunkún fún ara wọn, àmọ́ Dáfídì ló sunkún jù.
-
-
1 Sámúẹ́lì 23:16-18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
16 Ni Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù bá lọ sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hóréṣì, ó sì ràn án lọ́wọ́ kí ó lè túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé* Jèhófà.+ 17 Ó sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù, torí pé Sọ́ọ̀lù bàbá mi kò ní rí ọ mú; ìwọ lo máa di ọba Ísírẹ́lì,+ èmi ni màá di igbá kejì rẹ; Sọ́ọ̀lù bàbá mi náà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀.”+ 18 Àwọn méjèèjì wá dá májẹ̀mú+ níwájú Jèhófà, Dáfídì dúró sí Hóréṣì, Jónátánì sì gba ilé rẹ̀ lọ.
-