-
1 Kíróníkà 11:22-25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà jẹ́ akíkanjú ọkùnrin* tó gbé ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe ní Kábúséélì.+ Ó pa àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Áríélì ará Móábù bí, ó wọ inú kòtò omi lọ́jọ́ kan tí yìnyín bolẹ̀, ó sì pa kìnnìún.+ 23 Ó tún mú ọkùnrin ará Íjíbítì kan tó tóbi fàkìàfakia balẹ̀ tó ga ní ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún.*+ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kọ̀ tó wà ní ọwọ́ ará Íjíbítì náà dà bí ọ̀pá àwọn ahunṣọ,*+ ó fi ọ̀pá bá a jà, ó já ọ̀kọ̀ náà gbà ní ọwọ́ ará Íjíbítì náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ òun fúnra rẹ̀ pa á.+ 24 Àwọn ohun tí Bẹnáyà ọmọ Jèhóádà ṣe nìyẹn, ó lórúkọ bí àwọn akíkanjú jagunjagun mẹ́ta náà. 25 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ta yọ ju àwọn ọgbọ̀n (30) náà, kò wọ ẹgbẹ́ àwọn mẹ́ta àkọ́kọ́.+ Àmọ́ Dáfídì yàn án ṣe olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.
-
-
Òwe 30:30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 Kìnnìún, tó jẹ́ pé òun ló lágbára jù nínú àwọn ẹranko,
Tí kì í sì í yíjú pa dà níwájú ẹnikẹ́ni;+
-