ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Kíróníkà 21:8-13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 8 Dáfídì wá sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Mo ti dá ẹ̀ṣẹ̀+ ńlá nítorí ohun tí mo ṣe yìí. Ní báyìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ jì í,+ nítorí mo ti hùwà òmùgọ̀ gan-an.”+ 9 Lẹ́yìn náà, Jèhófà bá Gádì+ tó jẹ́ aríran Dáfídì sọ̀rọ̀, ó ní: 10 “Lọ sọ fún Dáfídì pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ohun mẹ́ta ni màá fi síwájú rẹ. Mú ọ̀kan tí o fẹ́ kí n ṣe sí ọ.”’” 11 Torí náà, Gádì wá sọ́dọ̀ Dáfídì, ó sì sọ fún un pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Mú èyí tí o bá fẹ́, 12 bóyá kí ìyàn+ fi ọdún mẹ́ta mú tàbí kí àwọn ọ̀tá rẹ fi oṣù mẹ́ta gbá ọ dà nù bí idà àwọn ọ̀tá rẹ ti ń lé ọ bá+ tàbí kí idà Jèhófà, ìyẹn àjàkálẹ̀ àrùn ní ilẹ̀ yìí,+ fi ọjọ́ mẹ́ta jà, kí áńgẹ́lì Jèhófà sì máa pani run+ ní gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì.’ Ní báyìí, ro ohun tí o fẹ́ kí n sọ fún Ẹni tó rán mi.” 13 Nítorí náà, Dáfídì sọ fún Gádì pé: “Ọ̀rọ̀ yìí kó ìdààmú bá mi gan-an. Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ Jèhófà, nítorí àánú rẹ̀ pọ̀ gidigidi;+ ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ èèyàn.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́