ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Sámúẹ́lì 24:10-14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 Àmọ́ ọkàn* Dáfídì dá a lẹ́bi+ lẹ́yìn tó ti ka iye àwọn èèyàn náà. Dáfídì wá sọ fún Jèhófà pé: “Mo ti dá ẹ̀ṣẹ̀+ ńlá nítorí ohun tí mo ṣe yìí. Ní báyìí, Jèhófà, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ jì í,+ nítorí mo ti hùwà òmùgọ̀ gan-an.”+ 11 Nígbà tí Dáfídì dìde ní àárọ̀, Jèhófà bá wòlíì Gádì+ tó jẹ́ aríran Dáfídì sọ̀rọ̀, ó ní: 12 “Lọ sọ fún Dáfídì pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ohun mẹ́ta ni màá fi síwájú rẹ. Mú ọ̀kan tí o fẹ́ kí n ṣe sí ọ.”’”+ 13 Torí náà, Gádì wá sọ́dọ̀ Dáfídì, ó sì sọ fún un pé: “Ṣé kí ìyàn ọdún méje mú ní ilẹ̀ rẹ?+ Tàbí kí o fi oṣù mẹ́ta máa sá fún àwọn ọ̀tá rẹ nígbà tí wọ́n bá ń lépa rẹ?+ Tàbí kí àjàkálẹ̀ àrùn fi ọjọ́ mẹ́ta jà ní ilẹ̀ rẹ?+ Ní báyìí, fara balẹ̀, kí o ro ohun tí o fẹ́ kí n sọ fún Ẹni tó rán mi.” 14 Nítorí náà, Dáfídì sọ fún Gádì pé: “Ọ̀rọ̀ yìí kó ìdààmú bá mi gan-an. Jọ̀wọ́, jẹ́ kí a ṣubú sí ọwọ́ Jèhófà,+ nítorí àánú rẹ̀ pọ̀;+ ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí n ṣubú sí ọwọ́ èèyàn.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́