Jẹ́nẹ́sísì 10:15, 16 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 15 Kénáánì bí Sídónì+ àkọ́bí rẹ̀ àti Hétì+ 16 àti àwọn ará Jébúsì,+ àwọn Ámórì,+ àwọn Gẹ́gáṣì, Jóṣúà 15:8 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 8 Ààlà náà dé Àfonífojì Ọmọ Hínómù,+ ó dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn ará Jébúsì+ ní gúúsù, ìyẹn Jerúsálẹ́mù,+ ààlà náà dé orí òkè tó dojú kọ Àfonífojì Hínómù lápá ìwọ̀ oòrùn, èyí tó wà ní ìkángun Àfonífojì* Réfáímù lápá àríwá.
8 Ààlà náà dé Àfonífojì Ọmọ Hínómù,+ ó dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àwọn ará Jébúsì+ ní gúúsù, ìyẹn Jerúsálẹ́mù,+ ààlà náà dé orí òkè tó dojú kọ Àfonífojì Hínómù lápá ìwọ̀ oòrùn, èyí tó wà ní ìkángun Àfonífojì* Réfáímù lápá àríwá.