-
2 Kíróníkà 4:18-22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Sólómọ́nì ṣe gbogbo nǹkan èlò yìí, wọ́n sì pọ̀ gan-an; a kò mọ bí ìwọ̀n bàbà náà ṣe pọ̀ tó.+
19 Sólómọ́nì ṣe gbogbo nǹkan èlò+ ilé Ọlọ́run tòótọ́: pẹpẹ wúrà;+ àwọn tábìlì+ tí búrẹ́dì àfihàn wà lórí wọn;+ 20 àwọn ọ̀pá fìtílà àti fìtílà wọn tí a fi ògidì wúrà ṣe,+ tí á máa jó níwájú yàrá inú lọ́hùn-ún gẹ́gẹ́ bí ìlànà ṣe sọ; 21 àwọn ìtànná òdòdó, àwọn fìtílà, àwọn ìpaná* tí a fi wúrà ṣe, tó jẹ́ ògidì wúrà pọ́ńbélé; 22 àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa fìtílà, àwọn abọ́, àwọn ife àti àwọn ìkóná tí a fi ògidì wúrà ṣe; ẹnu ọ̀nà ilé náà, àwọn ilẹ̀kùn rẹ̀ ti inú Ibi Mímọ́ Jù Lọ+ àti àwọn ilẹ̀kùn ilé tẹ́ńpìlì tí a fi wúrà ṣe.+
-