20 Lẹ́yìn náà, Dáfídì sọ fún Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ pé: “Jẹ́ onígboyà àti alágbára kí o sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Má bẹ̀rù, má sì jáyà, nítorí Jèhófà Ọlọ́run, Ọlọ́run mi, wà pẹ̀lú rẹ.+ Kò ní fi ọ́ sílẹ̀ tàbí kí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀,+ àmọ́ ó máa wà pẹ̀lú rẹ títí gbogbo iṣẹ́ tó jẹ́ ti iṣẹ́ ìsìn ilé Jèhófà á fi parí.