5 Wọ́n máa ń kó àwọn ẹran ọ̀sìn àtàwọn àgọ́ wọn tí wọ́n pọ̀ rẹpẹtẹ bí eéṣú+ wá, àwọn àtàwọn ràkúnmí wọn kì í níye,+ wọ́n á sì wá sí ilẹ̀ náà láti run ún. 6 Ísírẹ́lì wá tòṣì gan-an torí Mídíánì; àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ké pe Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́.+
5 Àwọn Filísínì pẹ̀lú kóra jọ láti bá Ísírẹ́lì jà, wọ́n ní ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ (30,000) kẹ̀kẹ́ ogun àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) agẹṣin àti àwọn ọmọ ogun tó pọ̀ bí iyanrìn etí òkun;+ wọ́n jáde lọ, wọ́n sì tẹ̀ dó sí Míkímáṣì ní ìlà oòrùn Bẹti-áfénì.+
7 “Ẹ jẹ́ onígboyà àti alágbára. Ẹ má bẹ̀rù, ẹ má sì jáyà nítorí ọba Ásíríà+ àti gbogbo ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ̀, torí àwọn tó wà pẹ̀lú wa pọ̀ ju àwọn tó wà pẹ̀lú rẹ̀.+