29 Nítorí náà, Ọba Jèhórámù pa dà sí Jésírẹ́lì+ kó lè tọ́jú ọgbẹ́ tí àwọn ará Síríà dá sí i lára ní Rámà nígbà tó ń bá Hásáẹ́lì ọba Síríà jà.+ Ahasáyà ọmọ Jèhórámù ọba Júdà lọ wo Jèhórámù ọmọ Áhábù ní Jésírẹ́lì, torí wọ́n ti ṣe é léṣe.*
7 Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fa ìṣubú Ahasáyà bó ṣe wá sọ́dọ̀ Jèhórámù; nígbà tó dé, ó tẹ̀ lé Jèhórámù lọ sọ́dọ̀ Jéhù+ ọmọ ọmọ* Nímúṣì, ẹni tí Jèhófà ti fòróró yàn láti pa ilé Áhábù run.*+