-
Jeremáyà 32:4, 5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Sedekáyà ọba Júdà kò ní lè sá mọ́ àwọn ará Kálídíà lọ́wọ́, nítorí ó dájú pé a ó fi í lé ọba Bábílónì lọ́wọ́, wọ́n á jọ rí ara wọn, wọ́n á sì sọ̀rọ̀ lójúkojú.”’+ 5 ‘Á mú Sedekáyà lọ sí Bábílónì, ibẹ̀ ló sì máa wà títí màá fi yíjú sí i,’ ni Jèhófà wí. ‘Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ ń bá àwọn ará Kálídíà jà, ẹ kò ní borí.’”+
-
-
Ìsíkíẹ́lì 12:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Ìjòyè àárín wọn yóò gbé ẹrù rẹ̀ lé èjìká, yóò sì lọ nínú òkùnkùn. Ó máa dá ògiri lu, yóò sì gbé ẹrù rẹ̀ gba inú ihò náà.+ Ó máa bo ojú rẹ̀ kó má bàa rí ilẹ̀.’ 13 Èmi yóò ju àwọ̀n mi sí i láti fi mú un.+ Màá wá mú un lọ sí Bábílónì, sí ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, àmọ́ kò ní rí i; ibẹ̀ ló sì máa kú sí.+
-