ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 25:6, 7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 6 Lẹ́yìn náà, wọ́n gbá ọba mú,+ wọ́n mú un wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbúlà, wọ́n sì dá a lẹ́jọ́. 7 Wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekáyà níṣojú rẹ̀; Nebukadinésárì wá fọ́ ojú Sedekáyà, ó fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é, ó sì mú un wá sí Bábílónì.+

  • Jeremáyà 38:17, 18
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 Jeremáyà wá sọ fún Sedekáyà pé: “Ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Bí o bá fi ara rẹ lé* àwọn ìjòyè ọba Bábílónì lọ́wọ́, wọ́n á dá ẹ̀mí rẹ sí,* wọn kò ní dáná sun ìlú yìí, wọn kò sì ní pa ìwọ àti agbo ilé rẹ.+ 18 Àmọ́, bí o kò bá fi ara rẹ lé* àwọn ìjòyè ọba Bábílónì lọ́wọ́, a ó fa ìlú yìí lé àwọn ará Kálídíà lọ́wọ́, wọ́n á dáná sun ún,+ o ò sì ní lè sá mọ́ wọn lọ́wọ́.’”+

  • Jeremáyà 39:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 5 Àmọ́ àwọn ọmọ ogun Kálídíà lé wọn, wọ́n sì bá Sedekáyà ní aṣálẹ̀ tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò.+ Wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un wá sọ́dọ̀ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì ní Ríbúlà+ ní ilẹ̀ Hámátì,+ ibẹ̀ ló sì ti dá a lẹ́jọ́.

  • Ìsíkíẹ́lì 12:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Èmi yóò ju àwọ̀n mi sí i láti fi mú un.+ Màá wá mú un lọ sí Bábílónì, sí ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, àmọ́ kò ní rí i; ibẹ̀ ló sì máa kú sí.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́