-
2 Kíróníkà 36:18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Gbogbo àwọn nǹkan èlò ilé Ọlọ́run tòótọ́, ńlá àti kékeré pẹ̀lú àwọn ìṣúra ilé Jèhófà àti àwọn ìṣúra ọba àti ti àwọn ìjòyè rẹ̀, gbogbo rẹ̀ pátá ló kó wá sí Bábílónì.+
-
-
Ẹ́sírà 1:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Ọba Kírúsì tún kó àwọn nǹkan èlò inú ilé Jèhófà jáde, àwọn tí Nebukadinésárì kó láti Jerúsálẹ́mù, tó sì kó sínú ilé ọlọ́run rẹ̀.+
-
-
Ẹ́sírà 1:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 ọgbọ̀n (30) abọ́ kékeré tí wọ́n fi wúrà ṣe, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mẹ́wàá (410) abọ́ kékeré tí wọ́n fi fàdákà ṣe àti ẹgbẹ̀rún kan (1,000) nǹkan èlò míì. 11 Gbogbo àwọn nǹkan èlò wúrà àti ti fàdákà jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (5,400). Gbogbo nǹkan yìí ni Ṣẹṣibásà kó wá nígbà tí wọ́n kó àwọn tó wà nígbèkùn+ kúrò ní Bábílónì wá sí Jerúsálẹ́mù.
-