-
1 Sámúẹ́lì 31:11-13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Nígbà tí àwọn tó ń gbé ní Jabeṣi-gílíádì+ gbọ́ ohun tí àwọn Filísínì ṣe sí Sọ́ọ̀lù, 12 gbogbo àwọn jagunjagun gbéra, wọ́n sì rìnrìn àjò ní gbogbo òru, wọ́n gbé òkú Sọ́ọ̀lù àti àwọn ọmọ rẹ̀ kúrò lára ògiri Bẹti-ṣánì. Wọ́n pa dà sí Jábéṣì, wọ́n sì sun wọ́n níbẹ̀. 13 Wọ́n wá kó egungun wọn,+ wọ́n sin wọ́n sábẹ́ igi támáríkì ní Jábéṣì,+ wọ́n sì fi ọjọ́ méje gbààwẹ̀.
-