ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Àwọn Ọba 7:51
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 51 Torí náà, Ọba Sólómọ́nì parí gbogbo iṣẹ́ ilé Jèhófà tó yẹ ní ṣíṣe. Lẹ́yìn náà, Sólómọ́nì kó àwọn ohun tí Dáfídì bàbá rẹ̀ ti yà sí mímọ́+ wọlé, ó kó fàdákà, wúrà àti àwọn ohun èlò wá sínú ibi tí wọ́n ń kó ìṣúra sí ní ilé Jèhófà.+

  • 1 Àwọn Ọba 14:25, 26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Ní ọdún karùn-ún Ọba Rèhóbóámù, Ṣíṣákì+ ọba Íjíbítì wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù.+ 26 Ó kó àwọn ìṣúra ilé Jèhófà àti ìṣúra ilé* ọba.+ Gbogbo nǹkan pátá ló kó, títí kan gbogbo apata wúrà tí Sólómọ́nì ṣe.+

  • 1 Kíróníkà 9:26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 Àwọn olórí* aṣọ́bodè mẹ́rin ló wà ní ipò ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Ọmọ Léfì ni wọ́n, àwọn ló sì ń bójú tó àwọn yàrá* àti àwọn ibi ìṣúra tó wà nínú ilé Ọlọ́run tòótọ́.+

  • 1 Kíróníkà 18:10, 11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó rán Hádórámù ọmọkùnrin rẹ̀ sí Ọba Dáfídì pé kí ó lọ béèrè àlàáfíà rẹ̀, kí ó sì bá a yọ̀ torí pé ó ti bá Hadadésà jà, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ (nítorí Hadadésà ti máa ń bá Tóù jà tẹ́lẹ̀), ó sì kó oríṣiríṣi ohun èlò wúrà, ohun èlò fàdákà àti ohun èlò bàbà wá. 11 Ọba Dáfídì yà wọ́n sí mímọ́ fún Jèhófà+ pẹ̀lú fàdákà àti wúrà tó kó lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yìí: láti Édómù àti Móábù, látọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ámónì,+ àwọn Filísínì+ àti àwọn ọmọ Ámálékì.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́