20 Ní àkókò náà, Hẹsikáyà ṣàìsàn dé ojú ikú.+ Wòlíì Àìsáyà ọmọ Émọ́ọ̀sì wá bá a, ó sì sọ fún un pé, “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Sọ ohun tí agbo ilé rẹ máa ṣe fún wọn, torí pé o máa kú; o ò ní yè é.’”+ 2 Ni ó bá yíjú sí ògiri, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà, ó ní: