27 Hírámù kó ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun+ rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ òkun tó mọṣẹ́, láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì. 28 Wọ́n lọ sí Ófírì,+ wọ́n sì kó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ogún (420) tálẹ́ńtì wúrà láti ibẹ̀ wá fún Ọba Sólómọ́nì.
22 Ọba ní ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun Táṣíṣì+ lórí òkun pẹ̀lú ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun ti Hírámù. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún mẹ́ta ni ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun Táṣíṣì máa ń kó wúrà àti fàdákà, eyín erin,+ àwọn ìnàkí àti àwọn ẹyẹ ọ̀kín wọlé.
18 Hírámù+ fi àwọn ọkọ̀ òkun àti àwọn òṣìṣẹ́ ọkọ̀ òkun tó mọṣẹ́ ránṣẹ́ sí Sólómọ́nì nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Wọ́n bá àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì lọ sí Ófírì,+ wọ́n sì kó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé àádọ́ta (450) tálẹ́ńtì* wúrà+ láti ibẹ̀ wá fún Ọba Sólómọ́nì.+