26 Ẹnì kan wà tó ń jẹ́ Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì nínú ẹ̀yà Éfúrémù, ó wá láti Sérédà, ìránṣẹ́ Sólómọ́nì+ ni. Sérúà lorúkọ ìyá rẹ̀, opó sì ni. Òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀tẹ̀ sí ọba.+ 27 Ohun tó jẹ́ kó ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ni pé: Sólómọ́nì mọ Òkìtì,+ ó sì dí àlàfo Ìlú Dáfídì bàbá rẹ̀.+