-
Ẹ́kísódù 30:12-16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 “Nígbàkigbà tí o bá ka iye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ kí kálukú mú ohun tí yóò fi ra ẹ̀mí* rẹ̀ pa dà wá fún Jèhófà nígbà ìkànìyàn náà. Èyí ò ní jẹ́ kí ìyọnu kankan ṣẹlẹ̀ sí wọn nígbà tí wọ́n bá forúkọ wọn sílẹ̀. 13 Ohun tí gbogbo àwọn tó bá forúkọ sílẹ̀ máa mú wá nìyí: ààbọ̀ ṣékélì,* kó jẹ́ ìwọ̀n ṣékélì ibi mímọ́.*+ Ogún (20) òṣùwọ̀n gérà* ni ṣékélì kan. Ààbọ̀ ṣékélì ni ọrẹ fún Jèhófà.+ 14 Kí gbogbo ẹni tó bá forúkọ sílẹ̀, tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè mú ọrẹ wá fún Jèhófà.+ 15 Kí ọlọ́rọ̀ má ṣe mú ohun tó ju ààbọ̀ ṣékélì* wá, kí aláìní má sì mú ohun tó kéré síyẹn wá láti fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà kí ẹ lè fi ṣe ètùtù fún ẹ̀mí* yín. 16 Kí o gba owó fàdákà fún ètùtù lọ́wọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì mú un wá fún iṣẹ́ àgọ́ ìpàdé, kó lè jẹ́ ohun ìrántí níwájú Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, láti ṣe ètùtù fún ẹ̀mí* yín.”
-