-
2 Àwọn Ọba 24:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Jèhóákínì ọba Júdà jáde lọ bá ọba Bábílónì,+ òun àti ìyá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀;+ ọba Bábílónì sì mú un lẹ́rú ní ọdún kẹjọ ìṣàkóso rẹ̀.+ 13 Lẹ́yìn náà, ó kó gbogbo ìṣúra ilé Jèhófà àti ìṣúra ilé* ọba jáde kúrò.+ Gbogbo nǹkan èlò wúrà tí Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì ṣe sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà+ ni ó gé sí wẹ́wẹ́. Èyí ṣẹlẹ̀ bí Jèhófà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́lẹ́.
-
-
2 Àwọn Ọba 25:13-15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Àwọn ará Kálídíà fọ́ àwọn òpó bàbà+ ilé Jèhófà àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù+ àti Òkun bàbà+ tó wà ní ilé Jèhófà sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì kó àwọn bàbà náà lọ sí Bábílónì.+ 14 Wọ́n tún kó àwọn garawa, àwọn ṣọ́bìrì, àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa fìtílà, àwọn ife àti gbogbo nǹkan èlò bàbà tí wọ́n ń lò nínú tẹ́ńpìlì. 15 Olórí ẹ̀ṣọ́ kó àwọn ìkóná àti àwọn abọ́ tí wọ́n fi ojúlówó wúrà+ ṣe àti àwọn tí wọ́n fi ojúlówó fàdákà+ ṣe.
-