33 Tí àwọn ọmọ Léfì ò bá ra ohun ìní wọn pa dà, kí ilé tí wọ́n tà nínú ìlú wọn pa dà di tiwọn nígbà Júbílì,+ torí àwọn ilé tó wà nínú àwọn ìlú àwọn ọmọ Léfì jẹ́ ohun ìní wọn láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 34 Bákan náà, ẹ má ta ibi ìjẹko+ tó yí àwọn ìlú wọn ká, torí ohun ìní wọn ló jẹ́ títí láé.