-
Nehemáyà 7:8-38Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 àwọn ọmọ Páróṣì jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé méjìléláàádọ́sàn-án (2,172); 9 àwọn ọmọ Ṣẹfatáyà jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé méjìléláàádọ́rin (372); 10 àwọn ọmọ Áráhì+ jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé méjìléláàádọ́ta (652); 11 àwọn ọmọ Pahati-móábù,+ látinú àwọn ọmọ Jéṣúà àti Jóábù+ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti méjìdínlógún (2,818); 12 àwọn ọmọ Élámù+ jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba àti mẹ́rìnléláàádọ́ta (1,254); 13 àwọn ọmọ Sátù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé márùnlélógójì (845); 14 àwọn ọmọ Sákáì jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé ọgọ́ta (760); 15 àwọn ọmọ Bínúì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé méjìdínláàádọ́ta (648); 16 àwọn ọmọ Bébáì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n (628); 17 àwọn ọmọ Ásígádì jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti méjìlélógún (2,322); 18 àwọn ọmọ Ádóníkámù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mẹ́tàdínláàádọ́rin (667); 19 àwọn ọmọ Bígífáì jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjì ó lé mẹ́tàdínláàádọ́rin (2,067); 20 àwọn ọmọ Ádínì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé márùndínlọ́gọ́ta (655); 21 àwọn ọmọ Átérì láti ilé Hẹsikáyà jẹ́ méjìdínlọ́gọ́rùn-ún (98); 22 àwọn ọmọ Háṣúmù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n (328); 23 àwọn ọmọ Bísáì jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé mẹ́rìnlélógún (324); 24 àwọn ọmọ Hárífù jẹ́ méjìléláàádọ́fà (112); 25 àwọn ọmọ Gíbíónì+ jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùn-ún (95); 26 àwọn ọkùnrin Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti Nétófà jẹ́ ọgọ́sàn-án ó lé mẹ́jọ (188); 27 àwọn ọkùnrin Ánátótì+ jẹ́ méjìdínláàádóje (128); 28 àwọn ọkùnrin Bẹti-ásímáfẹ́tì jẹ́ méjìlélógójì (42); 29 àwọn ọkùnrin Kiriati-jéárímù,+ Kéfírà àti Béérótì+ jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé mẹ́tàlélógójì (743); 30 àwọn ọkùnrin Rámà àti Gébà+ jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mọ́kànlélógún (621); 31 àwọn ọkùnrin Míkímásì+ jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà (122); 32 àwọn ọkùnrin Bẹ́tẹ́lì+ àti Áì+ jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123); 33 àwọn ọkùnrin Nébò kejì jẹ́ méjìléláàádọ́ta (52); 34 àwọn ọmọ Élámù kejì jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba àti mẹ́rìnléláàádọ́ta (1,254); 35 àwọn ọmọ Hárímù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé ogún (320); 36 àwọn ọmọ Jẹ́ríkò jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé márùnlélógójì (345); 37 àwọn ọmọ Lódì, Hádídì àti Ónò+ jẹ́ ọgọ́rùn-ún méje ó lé mọ́kànlélógún (721); 38 àwọn ọmọ Sénáà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án àti ọgbọ̀n (3,930).
-