-
Ẹ́kísódù 23:32Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
32 Ẹ ò gbọ́dọ̀ bá àwọn èèyàn náà tàbí àwọn ọlọ́run wọn dá májẹ̀mú.+
-
-
Ẹ́kísódù 34:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ má ṣe bá àwọn tó ń gbé ilẹ̀ náà dá májẹ̀mú, torí tí wọ́n bá ń bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe, tí wọ́n sì ń rúbọ sí àwọn ọlọ́run wọn,+ ẹnì kan yóò pè ọ́ wá, wàá sì jẹ nínú ẹbọ rẹ̀.+ 16 Ó sì dájú pé ẹ máa mú lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín,+ àwọn ọmọbìnrin wọn máa bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe, wọ́n á sì mú kí àwọn ọmọkùnrin yín bá àwọn ọlọ́run wọn ṣèṣekúṣe.+
-
-
Diutarónómì 7:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 O ò gbọ́dọ̀ bá wọn dána rárá.* O ò gbọ́dọ̀ fi àwọn ọmọbìnrin rẹ fún àwọn ọmọkùnrin wọn, o ò sì gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ.+ 4 Torí wọn ò ní jẹ́ kí àwọn ọmọkùnrin rẹ tọ̀ mí lẹ́yìn mọ́, wọ́n á mú kí wọ́n máa sin àwọn ọlọ́run míì;+ Jèhófà máa wá bínú gidigidi sí ọ, kíákíá ló sì máa pa ọ́ run.+
-
-
Jóṣúà 23:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 “Àmọ́ tí ẹ bá yí pa dà pẹ́nrẹ́n, tí ẹ sì rọ̀ mọ́ ìyókù àwọn orílẹ̀-èdè yìí, tí wọ́n ṣẹ́ kù+ pẹ̀lú yín, tí ẹ bá wọn dána,*+ tí ẹ sì ń bára yín ṣọ̀rẹ́, 13 kí ẹ mọ̀ dájú pé Jèhófà Ọlọ́run yín kò ní bá yín lé àwọn orílẹ̀-èdè yìí kúrò* mọ́.+ Wọ́n máa di pańpẹ́ àti ìdẹkùn fún yín, wọ́n máa di pàṣán ní ẹ̀gbẹ́ yín+ àti ẹ̀gún ní ojú yín, títí ẹ fi máa pa run lórí ilẹ̀ dáradára tí Jèhófà Ọlọ́run yín fún yín.
-