ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́sírà 5:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Bákan náà, látinú tẹ́ńpìlì Bábílónì, Ọba Kírúsì kó àwọn ohun èlò wúrà àti fàdákà ilé Ọlọ́run jáde, èyí tí Nebukadinésárì kó kúrò nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ sí tẹ́ńpìlì Bábílónì.+ Ọba Kírúsì kó wọn fún ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ṣẹṣibásà,*+ ẹni tí Kírúsì fi ṣe gómìnà.+

  • Ẹ́sírà 5:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Nígbà tí Ṣẹṣibásà yìí dé, ó fi ìpìlẹ̀ ilé Ọlọ́run lélẹ̀,+ èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù; àtìgbà yẹn ni wọ́n sì ti ń kọ́ ilé náà títí di báyìí, àmọ́ wọn ò tíì parí rẹ̀.’+

  • Hágáì 1:1
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 1 Ní ọdún kejì tí Ọba Dáríúsì ń ṣàkóso, ní oṣù kẹfà, ní ọjọ́ kìíní oṣù náà, Jèhófà rán wòlíì Hágáì*+ pé kó sọ fún Serubábélì+ ọmọ Ṣéálítíẹ́lì, gómìnà Júdà àti Jóṣúà ọmọ Jèhósádákì, àlùfáà àgbà pé:

  • Hágáì 1:14
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Torí náà, Jèhófà ru ẹ̀mí+ Serubábélì ọmọ Ṣéálítíẹ́lì, gómìnà Júdà+ sókè, ó tún ru ẹ̀mí Jóṣúà+ ọmọ Jèhósádákì, àlùfáà àgbà sókè àti ẹ̀mí gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù nínú àwọn èèyàn náà; wọ́n wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àtúnkọ́ ilé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun tó jẹ́ Ọlọ́run wọn.+

  • Hágáì 2:23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 “‘Ní ọjọ́ yẹn,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, ‘èmi yóò mú ìwọ ìránṣẹ́ mi, Serubábélì+ ọmọ Ṣéálítíẹ́lì,’+ ni Jèhófà wí, ‘èmi yóò sì ṣe ọ́ bí òrùka èdìdì, torí ìwọ ni ẹni tí mo yàn,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́