10 àmọ́ ọjọ́ keje jẹ́ sábáàtì fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ. O ò gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kankan, ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ àti ọmọbìnrin rẹ àti ẹrúkùnrin rẹ àti ẹrúbìnrin rẹ àti ẹran ọ̀sìn rẹ àti àjèjì tí ẹ jọ ń gbé.*+
2 Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, àmọ́ kí ọjọ́ keje jẹ́ mímọ́ fún yín. Kí ọjọ́ náà jẹ́ sábáàtì fún Jèhófà, ọjọ́ ìsinmi tí ẹ ò ní ṣiṣẹ́ rárá.+ Ṣe ni kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ náà.+