Jẹ́nẹ́sísì 3:19 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 19 Inú òógùn ojú rẹ ni wàá ti máa jẹun títí wàá fi pa dà sí ilẹ̀, torí inú rẹ̀ lo ti wá.+ Erùpẹ̀ ni ọ́, ìwọ yóò sì pa dà sí erùpẹ̀.”+ Sáàmù 49:17 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 17 Nítorí tí ó bá kú, kò lè mú ohunkóhun lọ;+Ògo rẹ̀ kò ní bá a sọ̀ kalẹ̀ lọ.+ Oníwàásù 5:15 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 15 Bí èèyàn ṣe jáde wá látinú ìyá rẹ̀ ní ìhòòhò, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe lọ.+ Kò lè mú ohunkóhun lọ nínú gbogbo iṣẹ́ àṣekára tó ti ṣe.+ Oníwàásù 12:7 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 7 Nígbà náà, erùpẹ̀ á pa dà sí ilẹ̀,+ bó ṣe wà tẹ́lẹ̀, ẹ̀mí* á sì pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ tó fúnni.+ 1 Tímótì 6:7 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 7 Torí a ò mú nǹkan kan wá sí ayé, a ò sì lè mú ohunkóhun jáde.+
19 Inú òógùn ojú rẹ ni wàá ti máa jẹun títí wàá fi pa dà sí ilẹ̀, torí inú rẹ̀ lo ti wá.+ Erùpẹ̀ ni ọ́, ìwọ yóò sì pa dà sí erùpẹ̀.”+
15 Bí èèyàn ṣe jáde wá látinú ìyá rẹ̀ ní ìhòòhò, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe lọ.+ Kò lè mú ohunkóhun lọ nínú gbogbo iṣẹ́ àṣekára tó ti ṣe.+
7 Nígbà náà, erùpẹ̀ á pa dà sí ilẹ̀,+ bó ṣe wà tẹ́lẹ̀, ẹ̀mí* á sì pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ tó fúnni.+