Sáàmù 37:10 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 10 Láìpẹ́, àwọn ẹni burúkú ò ní sí mọ́;+ Wàá wo ibi tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀,Wọn ò ní sí níbẹ̀.+ Sáàmù 92:7 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 7 Nígbà tí àwọn ẹni burúkú bá rú jáde bíi koríko*Tí gbogbo àwọn aṣebi sì gbilẹ̀,Kí wọ́n lè pa run títí láé ni.+ Jémíìsì 1:11 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 11 Bí oòrùn ṣe máa ń mú ooru tó ń jóni jáde tó bá yọ, tó sì máa mú kí ewéko rọ, tí òdòdó rẹ̀ á já bọ́, tí ẹwà rẹ̀ tó tàn sì máa ṣègbé, bẹ́ẹ̀ náà ni ọlọ́rọ̀ máa pa rẹ́ bó ṣe ń lépa ọrọ̀.+
7 Nígbà tí àwọn ẹni burúkú bá rú jáde bíi koríko*Tí gbogbo àwọn aṣebi sì gbilẹ̀,Kí wọ́n lè pa run títí láé ni.+
11 Bí oòrùn ṣe máa ń mú ooru tó ń jóni jáde tó bá yọ, tó sì máa mú kí ewéko rọ, tí òdòdó rẹ̀ á já bọ́, tí ẹwà rẹ̀ tó tàn sì máa ṣègbé, bẹ́ẹ̀ náà ni ọlọ́rọ̀ máa pa rẹ́ bó ṣe ń lépa ọrọ̀.+