-
Sáàmù 37:35Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
35 Mo ti rí ìkà ẹ̀dá tó jẹ́ olubi
Tó ń tẹ́ rẹrẹ bí igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ní ilẹ̀ tó dàgbà sí.+
-
-
Sáàmù 37:38Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
38 Àmọ́ a ó pa gbogbo àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rẹ́,
Ìparun ló sì ń dúró de àwọn ẹni burúkú ní ọjọ́ ọ̀la.+
-
-
Jeremáyà 12:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Olódodo ni ọ́, Jèhófà,+ nígbà tí mo gbé ẹjọ́ mi wá sọ́dọ̀ rẹ,
Nígbà tí mo sọ nípa ìdájọ́ òdodo fún ọ.
Àmọ́ kí nìdí tí ọ̀nà àwọn ẹni burúkú fi ń yọrí sí rere,+
Kí sì nìdí tí ọkàn àwọn oníbékebèke fi balẹ̀?
2 O gbìn wọ́n, wọ́n sì ti ta gbòǹgbò.
Wọ́n ti dàgbà, wọ́n sì ti so èso.
O wà lórí ètè wọn, ṣùgbọ́n èrò inú wọn* jìnnà sí ọ.+
Mú wọn bí àgùntàn tí wọ́n fẹ́ lọ pa,
Kí o sì yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ pípa.
-