Sáàmù 92:5 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 5 Àwọn iṣẹ́ rẹ mà tóbi o, Jèhófà!+ Èrò rẹ jinlẹ̀ gidigidi!+ Oníwàásù 3:11 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 11 Ó ti ṣe ohun gbogbo rèǹtèrente* ní ìgbà tirẹ̀.+ Kódà ó ti fi ayérayé sí wọn lọ́kàn; síbẹ̀ aráyé ò lè rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Àìsáyà 55:9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 9 “Torí bí ọ̀run ṣe ga ju ayé lọ,Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín,Èrò mi sì ga ju èrò yín.+
11 Ó ti ṣe ohun gbogbo rèǹtèrente* ní ìgbà tirẹ̀.+ Kódà ó ti fi ayérayé sí wọn lọ́kàn; síbẹ̀ aráyé ò lè rídìí iṣẹ́ tí Ọlọ́run tòótọ́ ti ṣe láé láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.