Jóòbù 34:19 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 19 Ẹnì kan wà tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn olórí,Tí kì í sì í ka ọlọ́rọ̀ sí ju aláìní lọ,*+Torí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn.+ Òwe 14:31 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 31 Ẹni tó ń lu aláìní ní jìbìtì ń gan Ẹni tó dá a,+Àmọ́ ẹni tó ń ṣàánú tálákà ń yìn Ín lógo.+ Òwe 22:2 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 2 Ohun tí ọlọ́rọ̀ àti aláìní fi jọra* ni pé: Jèhófà ló dá àwọn méjèèjì.+ Málákì 2:10 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 10 “Ṣebí bàbá kan ni gbogbo wa ní?+ Àbí Ọlọ́run kan náà kọ́ ló dá wa? Kí ló wá dé tí a fi ń dalẹ̀ ara wa,+ tí a sì ń pẹ̀gàn májẹ̀mú àwọn baba ńlá wa?
19 Ẹnì kan wà tí kì í ṣe ojúsàájú àwọn olórí,Tí kì í sì í ka ọlọ́rọ̀ sí ju aláìní lọ,*+Torí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni gbogbo wọn.+
10 “Ṣebí bàbá kan ni gbogbo wa ní?+ Àbí Ọlọ́run kan náà kọ́ ló dá wa? Kí ló wá dé tí a fi ń dalẹ̀ ara wa,+ tí a sì ń pẹ̀gàn májẹ̀mú àwọn baba ńlá wa?