13 Tí mi ò bá ka ẹ̀tọ́ àwọn ìránṣẹ́kùnrin tàbí ìránṣẹ́bìnrin mi sí,
Nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn kàn mí,
14 Kí ni mo lè ṣe tí Ọlọ́run bá kò mí lójú?
Kí ni mo lè sọ tó bá béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi?+
15 Ṣebí Ẹni tó dá mi nínú ilé ọlẹ̀ ló dá àwọn náà?+
Ǹjẹ́ kì í ṣe Ẹnì kan náà ló mọ wá kí wọ́n tó bí wa?+