ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 14:1-7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 14 Òmùgọ̀* sọ lọ́kàn rẹ̀ pé:

      “Kò sí Jèhófà.”+

      Ìwà ìbàjẹ́ ni wọ́n ń hù, ìṣesí wọn sì jẹ́ ohun ìríra;

      Kò sí ẹni tó ń ṣe rere.+

       2 Àmọ́ Jèhófà ń bojú wo àwọn ọmọ èèyàn láti ọ̀run

      Láti rí i bóyá ẹnì kan wà tó ní ìjìnlẹ̀ òye, bóyá ẹnì kan wà tó ń wá Jèhófà.+

       3 Gbogbo wọn ti kúrò lójú ọ̀nà;+

      Gbogbo wọn jẹ́ oníwà ìbàjẹ́.

      Kò sí ẹni tó ń ṣe rere,

      Kò tiẹ̀ sí ẹyọ kan.

       4 Ṣé kò yé ìkankan lára àwọn oníwà burúkú ni?

      Wọ́n ń ya àwọn èèyàn mi jẹ bí ẹni ń jẹ búrẹ́dì.

      Wọn ò ké pe Jèhófà.

       5 Àmọ́, jìnnìjìnnì á bò wọ́n,+

      Nítorí Jèhófà wà pẹ̀lú ìran àwọn olódodo.

       6 Ẹ̀yin oníwà burúkú fẹ́ da èrò aláìní rú,

      Àmọ́ Jèhófà ni ibi ààbò rẹ̀.+

       7 Ká ní ìgbàlà Ísírẹ́lì lè wá láti Síónì+ ni!

      Nígbà tí Jèhófà bá kó àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà lóko ẹrú pa dà,

      Kí inú Jékọ́bù dùn, kí Ísírẹ́lì sì yọ̀.

  • Róòmù 3:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 bó ṣe wà lákọsílẹ̀ pé: “Kò sí olódodo kankan, kò tiẹ̀ sí ẹyọ kan;+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́