46 Lónìí yìí, Jèhófà yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́,+ màá mú ọ balẹ̀, màá sì gé orí rẹ kúrò. Lónìí yìí kan náà, màá fi òkú àwọn tó wà ní ibùdó àwọn Filísínì fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹran inú igbó; gbogbo àwọn èèyàn tó wà láyé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run kan wà ní Ísírẹ́lì.+