ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 31:25-27
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 26 “Ka iye ẹrù tí wọ́n kó bọ̀ láti ogun, kí o ka iye èèyàn tí wọ́n kó lẹ́rú àtàwọn ẹran; ìwọ àti àlùfáà Élíásárì àti àwọn olórí agbo ilé bàbá wọn nínú àpéjọ náà ni kí ẹ jọ kà á. 27 Pín ẹrù tí wọ́n kó bọ̀ láti ogun sí méjì, kí ìdá kan jẹ́ ti àwọn ọmọ ogun tí wọ́n lọ jagun, kí ìdá kejì sì jẹ́ ti gbogbo àwọn yòókù nínú àpéjọ+ náà.

  • Jóṣúà 10:12
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 12 Lọ́jọ́ tí Jèhófà ṣẹ́gun àwọn Ámórì níṣojú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìgbà yẹn ni Jóṣúà sọ fún Jèhófà níṣojú Ísírẹ́lì pé:

      “Oòrùn, dúró sójú kan+ lórí Gíbíónì,+

      Àti òṣùpá, lórí Àfonífojì* Áíjálónì!”

  • Jóṣúà 10:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Àmọ́ àwọn ọba márààrún sá lọ, wọ́n sì lọ fara pa mọ́ sí inú ihò àpáta ní Mákédà.+

  • Jóṣúà 12:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 Ìwọ̀nyí ni àwọn ọba ilẹ̀ tí Jóṣúà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun lápá ìwọ̀ oòrùn Jọ́dánì, láti Baali-gádì,+ ní Àfonífojì Lẹ́bánónì+ títí dé Òkè Hálákì,+ tó lọ dé Séírì,+ tí Jóṣúà wá fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ àwọn ọba náà pé kó di tiwọn, bí ìpín wọn,+

  • Àwọn Onídàájọ́ 5:19
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 Àwọn ọba wá, wọ́n sì jà;

      Àwọn ọba Kénáánì wá jà  +

      Ní Táánákì, létí omi Mẹ́gídò.+

      Wọn ò kó+ fàdákà kankan lójú ogun.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́