-
Nọ́ńbà 31:27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Pín ẹrù tí wọ́n kó bọ̀ láti ogun sí méjì, kí ìdá kan jẹ́ ti àwọn ọmọ ogun tí wọ́n lọ jagun, kí ìdá kejì sì jẹ́ ti gbogbo àwọn yòókù nínú àpéjọ+ náà.
-
-
1 Sámúẹ́lì 30:23-25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
23 Àmọ́ Dáfídì sọ pé: “Ẹ má ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin arákùnrin mi, ẹ wo ohun tí Jèhófà fún wa. Ó dáàbò bò wá, ó sì fi àwọn jàǹdùkú* tó wá sọ́dọ̀ wa lé wa lọ́wọ́.+ 24 Ta ló máa fara mọ́ ohun tí ẹ sọ yìí? Ohun tí a máa pín fún ẹni tó lọ sójú ogun náà la máa pín fún ẹni tó jókòó ti ẹrù.+ Kálukú ló máa gba ìpín tirẹ̀.”+ 25 Láti ọjọ́ náà lọ, ó sọ ọ́ di ìlànà àti òfin fún Ísírẹ́lì títí di òní yìí.
-