25 Nígbà náà, Dáfídì àti àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì pẹ̀lú àwọn olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún jọ ń rìn lọ tayọ̀tayọ̀+ láti gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà wá láti ilé Obedi-édómù.+
28 Gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà bọ̀ pẹ̀lú igbe ayọ̀+ àti pẹ̀lú ìró ìwo àti kàkàkí+ pẹ̀lú síńbálì, wọ́n sì ń fi àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti háàpù+ kọrin sókè.