35 Aginjù àti ilẹ̀ tí kò lómi máa yọ̀,+
Aṣálẹ̀ tó tẹ́jú máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó sì máa yọ ìtànná bíi sáfúrónì.+
2 Ó dájú pé ó máa yọ ìtànná;+
Ó máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ó sì máa kígbe ayọ̀.
A máa fún un ní ògo Lẹ́bánónì,+
Ẹwà Kámẹ́lì+ àti ti Ṣárónì.+
Wọ́n máa rí ògo Jèhófà, ẹwà Ọlọ́run wa.