ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 4:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 Ní ọjọ́ yẹn, ohun tí Jèhófà mú kó rú jáde máa ga lọ́lá, ògo rẹ̀ sì máa yọ, èso ilẹ̀ náà máa jẹ́ ohun àmúyangàn àti ẹwà fún àwọn tó bá yè bọ́ ní Ísírẹ́lì.+

  • Àìsáyà 27:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Lọ́jọ́ iwájú, Jékọ́bù máa ta gbòǹgbò,

      Ísírẹ́lì máa yọ ìtànná, ó máa rú jáde,+

      Wọ́n sì máa fi irè oko kún ilẹ̀ náà.+

  • Àìsáyà 35:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Ní àkókò yẹn, ẹni tó yarọ máa fò sókè bí àgbọ̀nrín,+

      Ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ sì máa kígbe ayọ̀.+

      Torí omi máa tú jáde ní aginjù,

      Odò sì máa ṣàn ní aṣálẹ̀ tó tẹ́jú.

  • Àìsáyà 51:3
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  3 Torí Jèhófà máa tu Síónì nínú.+

      Ó máa tu gbogbo àwókù rẹ̀ nínú,+

      Ó máa mú kí aginjù rẹ̀ rí bí Édẹ́nì,+

      Ó sì máa mú kí aṣálẹ̀ rẹ̀ tó tẹ́jú rí bí ọgbà Jèhófà.+

      Ìdùnnú àti ayọ̀ máa wà níbẹ̀,

      Ìdúpẹ́ àti orin tó dùn.+

  • Ìsíkíẹ́lì 36:35
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 35 Àwọn èèyàn á sì sọ pé: “Ilẹ̀ tó ti di ahoro náà ti dà bí ọgbà Édẹ́nì,+ àwọn ìlú tó ti di àwókù, tó ti di ahoro, tí wọ́n sì ya lulẹ̀ ti wá ní odi, wọ́n sì ti ń gbé ibẹ̀.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́