-
Diutarónómì 6:21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 kí o sọ fún ọmọ rẹ pé, ‘A di ẹrú Fáráò ní Íjíbítì, àmọ́ Jèhófà fi ọwọ́ agbára mú wa jáde ní Íjíbítì.
-
-
Diutarónómì 11:18, 19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 “Kí ẹ rí i pé ẹ tẹ àwọn ọ̀rọ̀ mi yìí mọ́ ọkàn yín, kó sì di ara* yín, kí ẹ so ó mọ́ ọwọ́ yín bí ohun ìrántí, kó sì dà bí aṣọ ìwérí níwájú orí yín.*+ 19 Kí ẹ fi kọ́ àwọn ọmọ yín, kí ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà tí ẹ bá jókòó nínú ilé yín, tí ẹ bá ń rìn lójú ọ̀nà, tí ẹ bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí ẹ bá dìde.+
-
-
Jóṣúà 4:6, 7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 kí èyí jẹ́ àmì fún yín. Tí àwọn ọmọ* yín bá bi yín lọ́jọ́ iwájú pé, ‘Kí ni ẹ̀ ń fi àwọn òkúta yìí ṣe?’+ 7 kí ẹ sọ fún wọn pé: ‘Torí omi odò Jọ́dánì tó dáwọ́ dúró níwájú àpótí+ májẹ̀mú Jèhófà ni. Nígbà tí wọ́n gbé àpótí náà sọdá odò Jọ́dánì, omi odò Jọ́dánì dáwọ́ dúró. Àwọn òkúta yìí máa jẹ́ ohun ìrántí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí lọ.’”+
-