-
Sáàmù 81:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Àmọ́ àwọn èèyàn mi ò fetí sí ohùn mi;
Ísírẹ́lì kò ṣègbọràn sí mi.+
-
-
Jeremáyà 7:24-26Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sí mi, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sílẹ̀,+ kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń rìn nínú ètekéte* wọn, wọ́n ya alágídí, wọ́n sì ń ṣe ohun tí ọkàn búburú wọn sọ,+ ńṣe ni wọ́n ń pa dà sẹ́yìn, wọn ò lọ síwájú, 25 láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá yín ti jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì títí di òní.+ Torí náà, mò ń rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sí yín, mò ń rán wọn lójoojúmọ́, mo sì ń rán wọn léraléra.*+ 26 Ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sí mi, wọn kò sì fetí sílẹ̀.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ya alágídí,* wọ́n sì ṣe ohun tó burú ju ti àwọn baba ńlá wọn lọ!
-