-
2 Àwọn Ọba 24:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Jèhóákínì ọba Júdà jáde lọ bá ọba Bábílónì,+ òun àti ìyá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀;+ ọba Bábílónì sì mú un lẹ́rú ní ọdún kẹjọ ìṣàkóso rẹ̀.+ 13 Lẹ́yìn náà, ó kó gbogbo ìṣúra ilé Jèhófà àti ìṣúra ilé* ọba jáde kúrò.+ Gbogbo nǹkan èlò wúrà tí Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì ṣe sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà+ ni ó gé sí wẹ́wẹ́. Èyí ṣẹlẹ̀ bí Jèhófà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ gẹ́lẹ́.
-
-
Sáàmù 74:7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 Wọ́n sọ iná sí ibi mímọ́ rẹ.+
Wọ́n sọ àgọ́ ìjọsìn tí o fi orúkọ rẹ pè di aláìmọ́, wọ́n sì wó o lulẹ̀.
-