Sáàmù 77:20 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 20 O darí àwọn èèyàn rẹ bí agbo ẹran,+Lábẹ́ àbójútó* Mósè àti Áárónì.+ Àìsáyà 40:11 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 11 Ó máa bójú tó* agbo ẹran rẹ̀ bíi ti olùṣọ́ àgùntàn.+ Ó máa fi apá rẹ̀ kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọ,Ó sì máa gbé wọn sí àyà rẹ̀. Ó máa rọra da àwọn tó ń fọ́mọ lọ́mú.+ Jeremáyà 31:10 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 10 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,Ẹ sì kéde rẹ̀ láàárín àwọn erékùṣù tó jìnnà réré pé:+ “Ẹni tó tú Ísírẹ́lì ká máa kó o jọ. Á máa bójú tó o bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń bójú tó agbo ẹran rẹ̀.+ Ìsíkíẹ́lì 34:12 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 12 Èmi yóò bójú tó àwọn àgùntàn mi bí olùṣọ́ àgùntàn tó rí àwọn àgùntàn rẹ̀ tó fọ́n ká, tó sì ń fún wọn ní oúnjẹ.+ Èmi yóò gbà wọ́n sílẹ̀ kúrò ní gbogbo ibi tí wọ́n fọ́n ká sí ní ọjọ́ ìkùukùu* àti ìṣúdùdù tó kàmàmà.+ 1 Pétérù 2:25 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 25 Torí ẹ dà bí àwọn àgùntàn tó sọnù,+ àmọ́ ẹ ti wá pa dà sọ́dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn+ àti alábòójútó ọkàn* yín.
11 Ó máa bójú tó* agbo ẹran rẹ̀ bíi ti olùṣọ́ àgùntàn.+ Ó máa fi apá rẹ̀ kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọ,Ó sì máa gbé wọn sí àyà rẹ̀. Ó máa rọra da àwọn tó ń fọ́mọ lọ́mú.+
10 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,Ẹ sì kéde rẹ̀ láàárín àwọn erékùṣù tó jìnnà réré pé:+ “Ẹni tó tú Ísírẹ́lì ká máa kó o jọ. Á máa bójú tó o bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń bójú tó agbo ẹran rẹ̀.+
12 Èmi yóò bójú tó àwọn àgùntàn mi bí olùṣọ́ àgùntàn tó rí àwọn àgùntàn rẹ̀ tó fọ́n ká, tó sì ń fún wọn ní oúnjẹ.+ Èmi yóò gbà wọ́n sílẹ̀ kúrò ní gbogbo ibi tí wọ́n fọ́n ká sí ní ọjọ́ ìkùukùu* àti ìṣúdùdù tó kàmàmà.+
25 Torí ẹ dà bí àwọn àgùntàn tó sọnù,+ àmọ́ ẹ ti wá pa dà sọ́dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn+ àti alábòójútó ọkàn* yín.