-
Ẹ́kísódù 18:21, 22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
21 Àmọ́ kí o yan àwọn ọkùnrin tó kúnjú ìwọ̀n nínú àwọn èèyàn náà,+ àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí wọ́n ṣeé fọkàn tán, tí wọ́n sì kórìíra èrè tí kò tọ́,+ kí o wá fi àwọn yìí ṣe olórí wọn, kí wọ́n jẹ́ olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, olórí ọgọ́rọ̀ọ̀rún, olórí àràádọ́ta àti olórí mẹ́wàá-mẹ́wàá.+ 22 Kí wọ́n máa dá ẹjọ́ tí àwọn èèyàn náà bá gbé wá.* Kí wọ́n máa gbé gbogbo ẹjọ́ tó bá ṣòroó dá wá sọ́dọ̀ rẹ,+ àmọ́ kí wọ́n máa dá àwọn ẹjọ́ tí kò tó nǹkan. Jẹ́ kí wọ́n bá ọ gbé lára ẹrù yìí kí nǹkan lè rọrùn fún ọ.+
-