44 “Ní ọjọ́ àwọn ọba yẹn, Ọlọ́run ọ̀run máa gbé ìjọba kan kalẹ̀,+ tí kò ní pa run láé.+ A ò ní gbé ìjọba yìí fún èèyàn èyíkéyìí míì.+ Ó máa fọ́ àwọn ìjọba yìí túútúú,+ ó máa fòpin sí gbogbo wọn, òun nìkan ló sì máa dúró títí láé,+
26 Ẹni tó bá ṣẹ́gun, tó sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ mi títí dé òpin ni màá fún ní àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè,+27 ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn,+ kó lè fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ bí ohun èlò tí wọ́n fi amọ̀ ṣe, bí mo ṣe gbà á lọ́wọ́ Baba mi gẹ́lẹ́.