-
2 Sámúẹ́lì 7:12-15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Nígbà tí o bá kú,+ tí o sì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ, nígbà náà, màá gbé ọmọ* rẹ dìde lẹ́yìn rẹ, ọmọ ìwọ fúnra rẹ,* màá sì fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀.+ 13 Òun ló máa kọ́ ilé fún orúkọ mi,+ màá sì fìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ títí láé.+ 14 Màá di bàbá rẹ̀, á sì di ọmọ mi.+ Tí ó bá ṣe àìtọ́, màá fi ọ̀pá àti ẹgba àwọn ọmọ aráyé*+ bá a wí. 15 Ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ kò ní kúrò lára rẹ̀ bí mo ṣe mú un kúrò lára Sọ́ọ̀lù,+ ẹni tí mo mú kúrò níwájú rẹ.
-
-
Sáàmù 132:11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Jèhófà ti búra fún Dáfídì,
Ó dájú pé kò ní ṣàìmú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ pé:
-