-
1 Àwọn Ọba 8:25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
25 Ní báyìí, Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, mú ìlérí tí o ṣe fún ìránṣẹ́ rẹ Dáfídì bàbá mi ṣẹ, nígbà tí o sọ pé: ‘Kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà ìdílé rẹ níwájú mi tí yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì, bí àwọn ọmọ rẹ bá ṣáà ti ń fiyè sí ọ̀nà wọn, tí wọ́n sì ń rìn níwájú mi bí ìwọ náà ṣe rìn níwájú mi.’+
-
-
Jeremáyà 33:20, 21Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Bí ẹ bá lè ba májẹ̀mú mi nípa ọ̀sán àti májẹ̀mú mi nípa òru jẹ́, pé kí ọ̀sán àti òru má ṣe wà ní àkókò wọn+ 21 nìkan ni májẹ̀mú tí mo bá Dáfídì ìránṣẹ́ mi dá tó lè bà jẹ́,+ tí kò fi ní máa ní ọmọ tó ń jọba lórí ìtẹ́ rẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ náà ni májẹ̀mú tí mo bá àwọn àlùfáà tó jẹ́ ọmọ Léfì dá, àwọn òjíṣẹ́ mi.+
-