-
1 Kíróníkà 16:28-33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
28 Ẹ fún Jèhófà ní ohun tí ó tọ́ sí i, ẹ̀yin ìdílé gbogbo ayé,
Ẹ fún Jèhófà ní ohun tí ó tọ́ sí i nítorí ògo àti agbára rẹ̀.+
Ẹ forí balẹ̀ fún* Jèhófà nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ mímọ́.*+
30 Kí jìnnìjìnnì bá yín níwájú rẹ̀, gbogbo ayé!
Ayé* fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in; kò ṣeé ṣí nípò.*+
32 Kí òkun àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ dún bí ààrá;
Kí àwọn pápá àti gbogbo ohun tó wà lórí wọn máa dunnú.
33 Ní àkókò kan náà, kí àwọn igi igbó kígbe ayọ̀ níwájú Jèhófà,
Nítorí ó ń bọ̀ wá* ṣèdájọ́ ayé.
-
-
Sáàmù 29:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
29 Ẹ fún Jèhófà ní ohun tí ó tọ́ sí i, ẹ̀yin ọmọ àwọn alágbára,
Ẹ fún Jèhófà ní ohun tí ó tọ́ sí i nítorí ògo àti agbára rẹ̀.+
-