16 Àwọn àgbààgbà mẹ́rìnlélógún+ (24) tí wọ́n jókòó sórí ìtẹ́ wọn níwájú Ọlọ́run dojú bolẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn Ọlọ́run, 17 wọ́n ní: “A dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè, ẹni tó ti wà tipẹ́, tó sì wà báyìí,+ torí o ti gba agbára ńlá rẹ, o sì ti ń jọba.+