12 Kí ẹ máa yọ̀ níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín,+ ẹ̀yin àti àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, àwọn ẹrúkùnrin yín, àwọn ẹrúbìnrin yín àti ọmọ Léfì tó wà nínú àwọn ìlú* yín, torí wọn ò fún un ní ìpín tàbí ogún kankan pẹ̀lú yín.+
10 Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ, ẹ jẹ àwọn ohun tó dọ́ṣọ̀,* ẹ mu àwọn ohun dídùn, kí ẹ sì fi oúnjẹ ránṣẹ́+ sí àwọn tí kò ní nǹkan kan; nítorí ọjọ́ yìí jẹ́ mímọ́ lójú Olúwa wa, ẹ má sì banú jẹ́, nítorí ìdùnnú Jèhófà ni ibi ààbò* yín.”