6 Jèhófà ń kọjá níwájú rẹ̀, ó sì ń kéde pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú,+ tó ń gba tẹni rò,*+ tí kì í tètè bínú,+ tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀*+ àti òtítọ́*+ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi,
2 Torí náà, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Jèhófà, ṣebí ohun tí mo rò nígbà tí mo wà ní ilẹ̀ mi ló wá ṣẹlẹ̀ yìí? Torí ẹ̀ ni mo ṣe kọ́kọ́ sá lọ sí Táṣíṣì.+ Mo ti mọ̀ pé Ọlọ́run tó máa ń gba tẹni rò* ni ọ́, o jẹ́ aláàánú, o kì í tètè bínú,+ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ pọ̀ gidigidi, inú rẹ kì í sì í dùn sí àjálù.